1 Samuel 6:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n sì fi àwọn èkúté marun-un tí wọ́n fi wúrà ṣe ranṣẹ. Èkúté kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ìlú àwọn ọba Filistini maraarun. Àwọn maraarun wà fún àwọn ìlú olódi àwọn ọba Filistini, pẹlu àwọn ìletò kéékèèké wọn, tí kò ní odi. Àpáta ńlá tí ó wà ninu oko Joṣua ará Beti Ṣemeṣi, tí àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí OLUWA náà lé wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹliri wura na si ri gẹgẹ bi iye gbogbo ilu awọn Filistini ti o jasi ti awọn ijoye marun na, ati ilu, ati ilu olodi, ati awọn ileto, titi o fi de ibi okuta nla Abeli, lori eyi ti nwọn gbe apoti Oluwa kà: okuta eyiti o wà titi di oni ninu oko Joṣua ara Betṣemeṣi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Góòlù eku-ẹ̀lírí jẹ́ iye ìlú tí àwọn aláṣẹ Fílístínì márààrún ti wá, ìlú olodi pẹ̀lú ìlétò wọn. Àpáta ńlá náà, lórí èyí tí a gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA lé jẹ́ ẹ̀rí títí di òní ní oko Jóṣúà ará Bẹti-Sémésì.