1 Samuel 6:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Aadọrin ninu àwọn ará ìlú Beti Ṣemeṣi ni OLUWA pa, nítorí pé, wọ́n yọjú wo inú àpótí OLUWA náà. Àwọn eniyan náà sì ṣọ̀fọ̀ nítorí pé OLUWA pa ọpọlọpọ ninu wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si pọn awọn ọkunrin Betṣemeṣi loju, nitoriti nwọn bẹ inu apoti Oluwa wò, iye wọn ti o pa ninu awọn enia na jẹ ẹgbã mẹdọgbọn o le ãdọrin ọkunrin, awọn enia na pohunrere ẹkun nitoriti Oluwa fi iparun nla pa ọpọ̀ awọn enia na run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọ lu díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin Bẹti-Sémésì, ó pa àádọ́rin wọn, nítorí wọ́n ti wo inú àpótí ẹ̀rí OLÚWA. Àwọn ènìyàn ṣọ̀fọ̀ nítorí àjálù ńlá tí OLÚWA fi bá ọ̀pọ̀ wọn jà.