1 Samuel 6:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
àwọn ará ilẹ̀ náà pe àwọn babalóòṣà wọn ati àwọn adáhunṣe wọn jọ, wọ́n bi wọ́n pé, “Báwo ni kí á ti ṣe àpótí OLUWA? Bí a óo bá dá a pada sí ibi tí wọ́n ti gbé e wá, kí ni kí á fi ranṣẹ pẹlu rẹ̀?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn Filistini si pe awọn alufa ati awọn alasọtẹlẹ, wipe, Awa o ti ṣe apoti Oluwa si? sọ fun wa ohun ti awa o fi rán a lọ si ipò rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àwọn ará Fílístínì pe àwọn àlùfáà, àti àwọn aláṣọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì sọ pé, “Kí ni kí a ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí OLÚWA? Sọ fún wa bí àwa yóò ti dá a padà sí àyè rẹ̀.”