1 Samuel 6:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ óo bá dá àpótí Ọlọrun Israẹli pada, ẹ gbọdọ̀ dá a pada pẹlu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, àpótí ẹ̀rí náà kò gbọdọ̀ pada lọ lásán, láìsí nǹkan ètùtù. Bẹ́ẹ̀ ni ara yín yóo ṣe yá, ẹ óo sì mọ ìdí tí Ọlọrun fi ń jẹ yín níyà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wipe, Bi ẹnyin ba rán apoti Ọlọrun Israeli lọ, máṣe rán a lọ lofo; ṣugbọn bi o ti wu ki o ri, ẹ ṣe irubọ ẹbi fun u; a o si mu nyin lara da, ẹnyin o si mọ̀ ohun ti o ṣe ti ọwọ́ rẹ̀ kò fi kuro li ara nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n dáhùn wí pé, “Tí ẹ bá dá àpótí ẹ̀rí OLÚWA ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà, ẹ má ṣe dá a padà ní òfìfo, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fún un ní ẹbọ ẹ̀bi. Nígbà náà ni a ó mú un yín láradá, ẹ̀yin yóò sì mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi tí ì kúrò lára yín.”