1 Samuel 6:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan náà bi wọ́n pé, “Kí ni kí á fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù?” Àwọn babalóòṣà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún marun-un, ati ti èkúté marun-un, kí ẹ fi ranṣẹ. Kókó ọlọ́yún wúrà marun-un ati èkúté marun-un dúró fún àwọn ọba Filistini maraarun. Nítorí àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọlu gbogbo yín ati àwọn ọba yín maraarun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn wipe, Kini irubọ na ti a o fi fun u? Nwọn si dahun pe, Iyọdi wura marun, ati ẹ̀liri wura marun, gẹgẹ bi iye ijoye Filistini: nitoripe ajakalẹ arùn kanna li o wà li ara gbogbo nyin, ati awọn ijoye nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Fílístínì béèrè pé, “Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un?” Wọ́n dáhùn, “Góòlù oníkókó márùn ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn ún, gẹ́gẹ́ bí iye awọn aláṣẹ Fílístínì, nítorí àjàkálẹ̀-àrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín.