1 Samuel 6:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ gbọdọ̀ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún yín ati ti èkúté tí ń ba ilẹ̀ yín jẹ́, kí ẹ sì fi ògo fún Ọlọrun Israẹli bóyá ó lè dáwọ́ ìjìyà rẹ̀ dúró lórí ẹ̀yin ati oriṣa yín, ati ilẹ̀ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹnyin o ya ere iyọdi nyin, ati ere ẹ̀liri nyin ti o bà ilẹ na jẹ; ẹnyin o si fi ogo fun Ọlọrun Israeli: bọya yio mu ọwọ́ rẹ̀ fẹrẹ lara nyin, ati lara awọn ọlọrun nyin, ati kuro lori ilẹ nyin,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mọ àwòrán àrùn oníkókó àti ti eku èlírí yin tí ó ń ba orílẹ̀ èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín.