1 Samuel 6:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà ẹ kan kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun kan, kí ẹ sì tọ́jú abo mààlúù meji tí ń fún ọmọ lọ́mú tí ẹnikẹ́ni kò sì so àjàgà mọ́ lọ́rùn rí, ẹ so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, kí ẹ sì lé àwọn ọmọ wọn pada sílé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹ ṣe kẹkẹ titun kan nisisiyi, ki ẹ si mu abo malu meji ti o nfi ọmu fun ọmọ, eyi ti kò ti igbà ajaga si ọrun ri, ki ẹ si so o mọ kẹkẹ́ na, ki ẹnyin ki o si mu ọmọ wọn kuro lọdọ wọn wá ile.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nísinsìnyìí ẹ pèse kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun sílẹ̀, pẹ̀lú màlúù méjì tí ó ti fí ọmú fun ọmọ, èyí tí a kò tí ì fi ru ẹrù rí, kí ẹ sì so ó mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì mú ọmọ wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn wá sí ilé láti so.