1 Samuel 6:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ gbé àpótí OLUWA lé orí kẹ̀kẹ́ ẹrù náà. Ẹ kó àwọn kókó ọlọ́yún ati àwọn èkúté tí ẹ fi wúrà ṣe, tí ẹ fẹ́ fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù sinu àpótí kan, kí ẹ wá gbé e sí ẹ̀gbẹ́ àpótí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ẹ ti kẹ̀kẹ́ ẹrù yìí sójú ọ̀nà, kí ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ fúnrarẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o si gbe apoti Oluwa nì ka ori kẹkẹ̀ na, ki ẹnyin ki o si fi ohun elo wura wọnni ti ẹnyin dá fun u nitori ẹbọ ọrẹ irekọja, ninu apoti kan li apakan rẹ̀; ki ẹnyin rán a, yio si lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ sì gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA sí orí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kí ẹ̀yin sì kó àwọn ohun èlò wúrà tí ẹ̀yin fi fún un gẹ́gẹ́ bí ti ẹbọ ẹ̀bi sí inú àpótí ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì rán an lọ,