1 Samuel 6:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ máa kíyèsí i bí ó bá ti ń lọ. Bí ó bá doríkọ ọ̀nà ìlú Beti Ṣemeṣi, a jẹ́ pé Ọlọrun àwọn ọmọ Israẹli ni ó kó gbogbo àjálù yìí bá wa. Bí kò bá doríkọ ibẹ̀, a óo mọ̀ pé kì í ṣe òun ló rán àjálù náà sí wa, a jẹ́ pé ó kàn dé bá wa ni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹ si kiyesi i, bi o ba lọ si ọ̀na agbegbe tirẹ̀ si Betṣemeṣi, a jẹ pe on na li o ṣe wa ni buburu yi: ṣugbọn bi kò ba ṣe bẹ̃, nigbana li awa o to mọ̀ pe, ki iṣe ọwọ́ rẹ̀ li o lù wa, ṣugbọn ẽṣi li o ṣe si wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ṣùgbọ́n kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ. Tí ó bá ń lọ sí ilẹ̀ rẹ̀, ìlú rẹ̀, níhà Bẹti-Sémésì. Nígbà náà ni OLÚWA mú àjálù ńlá yìí bá wa. Ṣùgbọ́n bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà ni a mọ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ rẹ̀ ni ó kọ lù wá, ṣùgbọ́n ó wá bẹ́ẹ̀ ni”