1 Samuel 7:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará ìlú Kiriati Jearimu wá, wọ́n gbé àpótí OLUWA náà lọ sí ilé Abinadabu, tí ń gbé orí òkè kan. Wọ́n ya Eleasari, ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, láti máa bojútó àpótí OLUWA náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN ọkunrin Kirjatjearimu wá, nwọn gbe apoti Oluwa na, nwọn si mu u wá si ile Abinadabu ti o wà lori oke, nwọn si ya Eleasari ọmọ rẹ̀ si mimọ́ lati ma tọju apoti Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà àwọn ará Kiriáti-Jéárímù wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí OLÚWA. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Ábínádábù lórí òkè, wọ́n sì ya Élíásérì ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí OLÚWA.