1 Samuel 7:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Samuẹli ń rúbọ lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, láti bá wọn jagun. Ṣugbọn OLUWA sán ààrá lù wọ́n láti ọ̀run wá. Ìdààmú bá wọn, wọ́n sì túká pẹlu ìpayà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi Samueli ti nru ẹbọ sisun na lọwọ́, awọn Filistini si sunmọ Israeli lati ba wọn jà: ṣugbọn Oluwa sán ãrá nla li ọjọ na sori awọn Filistini, o si damu wọn, o si pa wọn niwaju Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Sámúẹ́lì ń ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun, àwọn Fílístínì súnmọ́ tòsí láti bá Ísírẹ́lì ja ogun. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà, OLÚWA sán àrá ńlá lu àwọn Fílístínì, ó sì mú jìnnìjìnnì bá wọn, a sì lé wọn níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.