1 Samuel 7:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹgun àwọn ará Filistia, wọn kò sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli mọ́. OLUWA n ṣe àwọn ará Filistia níbi ní gbogbo ọjọ́ ayé Samuẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li a tẹ ori awọn Filistini ba, nwọn kò si tun wá si agbegbe Israeli mọ: ọwọ́ Oluwa si wà ni ibi si awọn Filistini, ni gbogbo ọjọ Samueli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣẹ́gun Fílístínì, wọn kò sì wá sí agbégbé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́. Ní gbogbo ìgbésí ayé Sámúẹ́lì, ọwọ́ OLÚWA lòdì sí àwọn Fílístínì.