1 Samuel 7:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ìlú tí àwọn Filistini ti gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, láti Ekironi títí dé Gati, ni wọ́n dá pada fún wọn. Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ilẹ̀ wọn pada lọ́wọ́ àwọn ará Filistia. Alaafia wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará Amori.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ilu wọnni eyi ti awọn Filistini ti gbà lọwọ Israeli ni nwọn si fi fun Israeli, lati Ekroni wá titi o fi de Gati; ati agbegbe rẹ̀, ni Israeli gbà silẹ lọwọ́ awọn Filistini. Irẹpọ si wà larin Israeli ati awọn Amori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìlú láti Ékírónì dé Gátì tí àwọn Fílístínì ti gbà lọ́wọ́ Ísírẹ́lì ni ó ti gbà padà fún Ísírẹ́lì, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ agbègbè rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìṣàkóso àwọn Fílístínì. Ìrẹ́pọ̀ sì wà láàárin Ísírẹ́lì àti àwọn Ámórì.