1 Samuel 7:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Láti ìgbà náà, Kiriati Jearimu ni wọ́n gbé àpótí OLUWA sí fún nǹkan bíi ogún ọdún, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ń ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, lati igba ti apoti Oluwa fi wà ni Kirjatjearimu, ọjọ na pẹ́; o si jẹ ogun ọdun: gbogbo ile Israeli si pohunrere ẹkun si Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí OLÚWA fi wà ní Kiriati Jéárímù. Gbogbo ilé Ísírẹ́lì ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùn réré ẹkún sí OLÚWA.