1 Samuel 7:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹ bá fẹ́ pada sọ́dọ̀ OLUWA tọkàntọkàn, ẹ gbọdọ̀ kó gbogbo oriṣa ati gbogbo ère oriṣa Aṣitarotu, tí ó wà lọ́dọ̀ yín dànù; ẹ palẹ̀ ọkàn yín mọ́ fún OLUWA, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo; yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli si sọ fun gbogbo ile Israeli, wipe, Bi ẹnyin ba fi gbogbo ọkàn nyin yipada si Oluwa, ẹ mu ajeji ọlọrun wọnni, ati Aṣtaroti kuro larin nyin, ki ẹnyin ki o si pese ọkàn nyin silẹ fun Oluwa, ki ẹ si ma sin on nikanṣoṣo: yio si gbà nyin lọwọ́ Filistini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúẹ́lì sọ fún gbogbo ilé Ísírẹ́lì pé, “Tí ẹ bá ń padà sí ọ̀dọ̀ OLÚWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, Ẹ yẹra kúrò lọ́dọ̀ ọlọ́run àjòjì àti Áṣitarótì kí ẹ sì farayín jìn fún OLÚWA kí ẹ sì sin òun nìkan ṣoṣo, òun yóò sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Fílístínì”