1 Samuel 7:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo wọn bá péjọ sí Misipa, wọ́n pọn omi, wọ́n dà á sílẹ̀, wọ́n sì ṣe ètùtù níwájú OLUWA. Wọ́n gbààwẹ̀ ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ sí OLUWA.” Samuẹli sì ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan Israẹli ní Misipa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si pejọ si Mispe, nwọn pọn omi, nwọn si tú u silẹ niwaju Oluwa, nwọn gbawẹ li ọjọ na, nwọn si wi nibẹ pe, Awa ti dẹṣẹ si Oluwa. Samueli si ṣe idajọ awọn ọmọ Israeli ni Mispe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n sì ti péjọpọ̀ ní Mísípà, wọ́n pọn omi, wọ́n sì dà á sílẹ̀ níwájú OLÚWA. Ní ọjọ́ náà, wọ́n gba ààwẹ̀, wọ́n sì jẹ́wọ́ pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí OLÚWA.” Sámúẹ́lì sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Mísípà.