1 Samuel 7:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Samuẹli pa ọmọ aguntan kan tí ó ṣì ń mu ọmú, ó sun ún lódidi, ó fi rúbọ sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó gbadura sí OLUWA fún ìrànlọ́wọ́ Israẹli; OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli mu ọdọ-agutan kan ti nmu ọmu, o si fi i ru ọtọtọ ẹbọ sisun si Oluwa: Samueli si ke pe Oluwa fun Israeli; Oluwa si gbọ́ ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Sámúẹ́lì mú ọ̀dọ́ àgùntàn tí ó jẹ́ ọmọ ọmú, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí OLÚWA. Ó sí kè pe OLÚWA nítorí ilé Ísírẹ́lì, OLÚWA sì dá a lóhùn.