1 Samuel 8:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó ṣe àlàyé fún wọn pé, “Bí ọba yín yóo ti máa ṣe yín nìyí: Yóo sọ àwọn ọmọkunrin yín di ọmọ ogun, àwọn kan ninu wọn yóo máa wa kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn kan yóo wà ninu ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń fi ẹsẹ̀ rìn, àwọn kan yóo máa gun ẹṣin níwájú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Eyi ni yio ṣe ìwa ọba na ti yio jẹ lori nyin: yio mu awọn ọmọkunrin nyin, yio si yàn wọn fun ara rẹ̀ fun awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati fun ẹlẹṣin rẹ̀, nwọn o si ma sare niwaju kẹkẹ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba tí yóò jẹ lórí yín yóò ṣe. Yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín, yóò sì mú wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti fún ẹlẹ́sin rẹ, wọn yóò sì máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ rẹ̀.