1 Samuel 8:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo fi àwọn kan ṣe ọ̀gágun fún ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun, àwọn kan yóo máa ṣe ọ̀gágun fún araadọta ọmọ ogun. Àwọn kan yóo máa ro oko rẹ̀, àwọn kan yóo sì máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀. Àwọn kan yóo máa rọ ohun ìjà fún un, ati àwọn ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si yan olori ẹgbẹgbẹrun fun ara rẹ̀, ati olori aradọta; yio si yàn wọn lati ma ro oko rẹ̀, ati lati ma kore fun u, ati lati ma ṣe ohun elo-ogun rẹ̀, ati ohun elo-kẹkẹ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò yan díẹ̀ láti jẹ́ olórí ẹgbẹ̀rún àti olórí àádọ́ta àti àwọn mìíràn. Yóò yan wọ́n láti máa tulẹ̀ oko rẹ̀ àti láti máa kórè rẹ̀ àti àwọn mìíràn láti máa ṣe ohun èlò ogun àti ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.