1 Samuel 8:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
wọ́n wí fún un pé, “Wò ó, àgbà ti dé sí ọ, àwọn ọmọ rẹ kò sì tẹ̀lé àpẹẹrẹ rere rẹ. Yan ẹnìkan, gẹ́gẹ́ bí ọba fún wa, tí yóo máa ṣe alákòóso wa bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun u pe, Kiye si i, iwọ di arugbo, awọn ọmọ rẹ kò si rin ni ìwa rẹ: njẹ fi ẹnikan jẹ ọba fun wa, ki o le ma ṣe idajọ wa, bi ti gbogbo orilẹ-ède.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ ti di arúgbó, àwọn ọmọ rẹ kò sì rìn ní ọ̀nà rẹ: Nísinsìn yìí, yan ọba fún wa kí or lè máa darí wa gẹ́gẹ́ bí i tí gbogbo orílẹ̀ èdè”