1 Samuel 9:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọbinrin náà dá wọn lóhùn pé, “Ó wà ní ìlú. Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá nisinsinyii ni. Bí ó ti ń wọ ìlú bọ̀ tààrà nìyí, ẹ yára lọ bá a. Àwọn eniyan ní ẹbọ kan tí wọn óo rú ní orí òkè lónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si da wọn lohùn, nwọn si wipe, O mbẹ; wo o, o mbẹ niwaju nyin: yara nisisiyi nitoripe loni li o de ilu; nitoriti ẹbọ mbẹ fun awọn enia loni ni ibi giga.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ó wà,” wọ́n dáhùn. “Ó ń bẹ níwájú u yín, múra nísinsìn yìí, ó ṣẹ̀ ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa lónìí ni, nítorí àwọn ènìyàn ní ẹbọ rírú ni ibi gíga.