1 Samuel 9:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹ bá tí ń wọ ìlú ni ẹ óo rí i. Ẹ yára kí ẹ lè bá a, kí ó tó lọ sí orí òkè lọ jẹun; nítorí pé àwọn eniyan kò ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóo fi dé. Òun ni ó gbọdọ̀ súre sí ẹbọ náà, kí àwọn tí wọ́n bá pè tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. Ẹ tètè máa lọ, ẹ óo bá a.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹnyin ti nlọ si ilu na, ẹnyin o si ri i, ki o to lọ si ibi giga lati jẹun: nitoripe awọn enia kì yio jẹun titi on o fi de, nitori on ni yio sure si ẹbọ na; lẹhin eyini li awọn ti a pè yio to jẹun. Ẹ goke lọ nisisiyi; lakoko yi ẹnyin o ri i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kété tí ẹ bá ti wọ ìlú, ẹ ó rí i kí ó tó lọ sí ibi gíga láti lọ jẹun. Àwọn ènìyàn kò sì ní bẹ̀rẹ̀ sí jẹun títí tí yóò fi dé. Torí ó gbúdọ̀ bùkún ẹbọ náà; lẹ́yìn náà, àwọn tí a pè yóò jẹun. Gòkè lọ nísinsìn yìí: ó yẹ kí ẹ rí i ní àkókò yìí.”