1 Samuel 9:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Samuẹli dá a lóhùn pé, “Èmi aríran náà nìyí. Ẹ máa lọ sí ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ, nítorí ẹ óo bá mi jẹun lónìí. Bí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, n óo jẹ́ kí ẹ lọ, n óo sì sọ gbogbo ohun tí ẹ fẹ́ mọ̀ fun yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samueli da Saulu lohùn o si wipe, emi ni arina na: goke lọ siwaju mi ni ibi giga, ẹ o si ba mi jẹun loni, li owurọ̀ emi o si jẹ ki o lọ, gbogbo eyi ti o wà li ọkàn rẹ li emi o sọ fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúẹ́lì dáhùn pé, “Èmi ni wòlíì náà. Ẹ máa gòkè lọ ṣáájú mi, ní ibi gíga, ẹ ó sì bá mi jẹun lónìí. Ní òwúrọ̀ ni èmi yóò tó jẹ́ kí ẹ lọ, gbogbo ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ ní èmi yóò sọ fún ọ.