1 Samuel 9:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Alásè náà bá gbé ẹsẹ̀ ati itan ẹran náà wá, ó gbé e kalẹ̀ níwájú Saulu. Samuẹli wí fún Saulu pé, “Wò ó, ohun tí a ti pèsè sílẹ̀ dè ọ́ ni wọ́n gbé ka iwájú rẹ yìí. Máa jẹ ẹ́, ìwọ ni a fi pamọ́ dè, pé kí o jẹ ẹ́ ní àkókò yìí pẹlu àwọn tí mo pè.” Saulu ati Samuẹli bá jọ jẹun pọ̀ ní ọjọ́ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alase na si gbe ejika na, ati eyi ti o wà lori rẹ̀, o si gbe e kalẹ niwaju Saulu. Samueli si wipe, Wo eyi ti a fi silẹ! fà a sọdọ rẹ, ki o si ma jẹ: nitoripe titi di isisiyi li ati pa a mọ fun ọ lati igbati mo ti wipe, emi ti pe awọn enia na. Bẹ̃ni Saulu si ba Samueli jẹun li ọjọ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Alásè náà sì gbé ẹṣẹ̀ náà pẹ̀lú ohun tí ó wà lórí i rẹ̀, ó sì gbé e ṣíwájú Ṣọ́ọ̀lù. Sámúẹ́lì wí pé, “Èyí ni ohun tí a fi pamọ́ fún ọ. Jẹ, nítorí a yà á sọ́tọ̀ fún ọ, fún ìdí yìí, láti ìgbà tí mo ti wí pé, ‘Mo ní àlejò tí a pè.’ ” Ṣọ́ọ̀lù sì jẹun pẹ̀lú Sámúẹ́lì ní ọjọ́ náà.