1 Samuel 9:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́júmọ́, Samuẹli pe Saulu lórí òrùlé, ó ní, “Dìde kí n sìn ọ́ sọ́nà.” Saulu dìde, òun ati Samuẹli bá jáde sí òpópónà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si dide ni kutukutu: o si ṣe, li afẹmọjumọ, Samueli si pe Saulu sori orule, wipe, Dide, emi o si ran ọ lọ. Saulu si dide, awọn mejeji sì jade, on ati Samueli, si gbangba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì dìde ní àfẹ̀mọ́jú, ó pe Ṣọ́ọ̀lù sórí òrùlé pé, “Múra, èmi yóò rán ọ lọ.” Nígbà tí Ṣọ́ọ̀lù múra tán òun àti Sámúẹ́lì jọ jáde lọ síta.