1 Samuel 9:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé ibi odi ìlú, Samuẹli wí fún Saulu pé, “Sọ fún iranṣẹ rẹ kí ó máa nìṣó níwájú dè wá.” Iranṣẹ náà bá bọ́ siwaju, ó ń lọ. Samuẹli sọ fún Saulu pé, “Dúró díẹ̀ níhìn-ín kí n sọ ohun tí Ọlọrun wí fún ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi nwọn si ti nsọkalẹ lọ si ipẹkun ilu na, Samueli wi fun Saulu pe, Wi fun iranṣẹ ki o kọja si iwaju wa, (o si kọja) ṣugbọn ki iwọ ki o duro diẹ, ki emi ki o le fi ọ̀rọ Ọlọrun hàn ọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìpẹ̀kun ìlú náà, Sámúẹ́lì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Sọ fún ìránṣẹ́ náà kí ó máa lọ ṣáájú u wa,” ìránṣẹ́ náà sì ṣe bẹ̀ẹ́, “ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó dúró díẹ̀, kí èmi kí ó lè sọ ọrọ̀ láti ọ̀dọ Ọlọ́run fún ọ.”