1 Samuel 9:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n wá gbogbo agbègbè olókè Efuraimu káàkiri, ati gbogbo agbègbè Ṣaliṣa, ṣugbọn wọn kò rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà. Wọ́n wá gbogbo agbègbè Ṣaalimu, ṣugbọn wọn kò rí wọn níbẹ̀. Lẹ́yìn náà wọ́n wá gbogbo ilẹ̀ Bẹnjamini, sibẹsibẹ wọn kò rí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On kọja niha oke Efraimu, o si kọja niha ilẹ Saliṣa, ṣugbọn nwọn kò ri wọn: nwọn si kọja ni ilẹ Salimu, nwọn kò si si nibẹ; o si kọja ni ilẹ Benjamini, nwọn kò si ri wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrin àwọn ìlú olókè Éfúráímù, ó sì kọja ní àyíká ilẹ̀ Sálísà, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn. Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Sálímù, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀. Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Bẹ́ńjámínì, wọn kò sì rí wọn.