1 Samuel 9:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé agbègbè Sufu, Saulu sọ fún iranṣẹ tí ó wà pẹlu rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á pada sílé, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi lè má ronú nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mọ́, kí ó máa páyà nítorí tiwa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn de ilẹ Sufu, Saulu wi fun iranṣẹ-kọnrin rẹ̀ ẹniti o wà lọdọ rẹ̀, pe, Wá, jẹ ki a yipada; ki baba mi ki o má ba fi ãjò awọn kẹtẹkẹtẹ silẹ, ki o si ma kọ ominu nitori wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n dé agbégbé Ṣúfù, Ṣọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí á padà sẹ́yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi yóò dá ìrònú rẹ̀ dúró nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yóò sì bẹ̀rẹ̀ àníyàn nípa wa.”