1 Samuel 9:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu dá a lóhùn pé, “Bí a bá tọ eniyan Ọlọrun yìí lọ nisinsinyii, kí ni a óo mú lọ́wọ́ lọ fún un? Oúnjẹ tí ó wà ninu àpò wa ti tán, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí nǹkankan lọ́wọ́ wa tí a lè fún un. Àbí kí ni a óo fún un?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Bi awa ba lọ, kili awa o mu lọ fun ọkunrin na? nitoripe akara tan ni apò wa, ko si si ọrẹ ti a o mu tọ̀ ẹni Ọlọrun na: kili awa ni?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀, “Tí àwa bá lọ, kín ni àwa lè fún ọkùnrin náà? Oúnjẹ inú àpò wa ti tán. A kò sì ní ẹ̀bùn láti mú lọ sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Kí ni a ní?”