1 Samuel 9:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
(Ní àtijọ́, ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Ọlọrun, yóo wí pé, òun ń lọ sí ọ̀dọ̀ aríran; nítorí àwọn tí àwa ń pè ní wolii lónìí, aríran ni wọ́n ń pè wọ́n nígbà náà.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
(Ni Israeli latijọ, nigbati ọkunrin kan ba lọ bere lọdọ Ọlọrun, bayi ni ima wi, Wá, ẹ jẹ ki a lọ sọdọ arina na, nitori ẹni ti a npe ni woli nisisiyi, on ni a npe ni arina nigba atijọ ri)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
(Tẹ́lẹ̀ ní Ísírẹ́lì tí ọkùnrin kan bá lọ béèrè lọ́dọ̀ Ọlọ́run, yóò wí pé, “Wá, Jẹ́ kí a lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì náà,” nítorí àwọn aláṣọtẹ́lẹ̀ ìsinsìn yìí ni wọ́n ń pè ní wòlíì).