1 Thessalonians 2:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, àwa náà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo, nítorí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ẹ gbọ́ lẹ́nu wa, ẹ gbà á bí ó ti rí gan-an ni. Bí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ẹ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ eniyan. Ọ̀rọ̀ náà sì ń ṣiṣẹ́ ninu ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori eyi li awa ṣe ndupẹ lọwọ Ọlọrun pẹlu li aisimi, pe nigbati ẹnyin gba ọ̀rọ ti ẹnyin gbọ lọdọ wa, ani ọ̀rọ Ọlọrun, ẹnyin kò gbà a bi ẹnipe ọ̀rọ enia, ṣugbọn gẹgẹ bi o ti jẹ nitõtọ, bi ọ̀rọ Ọlọrun, eyiti o ṣiṣẹ gidigidi ninu ẹnyin ti o gbagbọ́ pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.