1 Thessalonians 2:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn Juu yìí ni wọ́n pa Oluwa Jesu ati àwọn wolii, tí wọ́n sì fi inúnibíni lé wa jáde. Wọn kò ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun, wọ́n sì ń lòdì sí àwọn ohun tí ó lè ṣe eniyan ní anfaani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ẹniti o pa Jesu Oluwa, ati awọn woli, nwọn si tì wa jade; nwọn kò si ṣe eyiti o wu Ọlọrun, nwọn si wà lodi si gbogbo enia:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
àwọn tí wọ́n pa Jésù Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn