1 Thessalonians 2:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ń ṣe ìdínà fún wa kí á má baà lè waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu, kí wọn má baà rí ìgbàlà, kí òṣùnwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ wọn baà lè kún. Ṣugbọn ibinu Ọlọrun ti dé sórí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn kọ̀ fun wa lati sọ̀rọ fun awọn Keferi ki nwọn ki o le là, lati mã sọ ẹ̀ṣẹ wọn di kikun nigbagbogbo: ṣugbọn ibinu de bá wọn titi de opin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìyìnrere dúró láàrin àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀sẹ̀ wọn ń di púpọ̀ síi lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.