1 Thessalonians 2:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀yin ará, nígbà tí a kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pínyà nípa ti ara, sibẹ ọkàn wa kò kúrò lọ́dọ̀ yín, ọkàn yín tún ń fà wá gan-an ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn, ará, awa ti a gbà kuro lọdọ nyin fun sã kan li ara, ki iṣe li ọkàn, pẹlu itara ọpọlọpọ li awa ṣe aniyan ti a si fẹ gidigidi lati ri oju nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀yin ará olùfẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí a ti kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀ (nínú ara, kì í ṣe ọkàn), pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtara ni àwa ṣe àníyàn tí a sì fẹ́ gidigidi láti fi rí i yín.