1 Thessalonians 3:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí Oluwa fi agbára fun yín, kí ọkàn yín lè wà ní ipò mímọ́, láìní àléébù, níwájú Ọlọrun Baba wa nígbà tí Oluwa wa Jesu bá farahàn pẹlu gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o ba le fi ọkàn nyin balẹ li ailabukù ninu ìwa mimọ́ niwaju Ọlọrun ati Baba wa, nigba atiwá Jesu Kristi Oluwa wa pẹlu gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa èyí, ọkàn yín yóò di alágbára, àìlẹ́sẹ̀ àti Mímọ́ nípa Ọlọ́run, Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jésù Kírísítì yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.