1 Thessalonians 3:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ni a bá rán Timoti si yín, ẹni tí ó jẹ́ arakunrin wa ati alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun ninu iṣẹ́ ìyìn rere ti Kristi, kí ó lè máa gbà yín níyànjú, kí igbagbọ yín lè dúró gbọnin-gbọnin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa si rán Timotiu, arakunrin wa, ati iranṣẹ Ọlọrun ninu ihinrere Kristi, lati fi ẹsẹ nyin mulẹ, ati lati tù nyin ninu niti igbagbọ́ nyin:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì rán Tímótíù, arákùnrin àti alábáṣiṣẹ́ pọ̀ wá, láti bẹ̀ yín wò. Mo rán an láti fún ìgbàgbọ́ yín lágbára àti láti mú yín lọ́kà le; àti kí ó má sì ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, nínú ìṣòro tí ẹ ń là kọjá.