1 Thessalonians 3:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, èmi náà kò lè fi ara dà á mọ́, ni mo bá ranṣẹ láti wá wádìí nípa ìdúró yín, kí ó má baà jẹ́ pé olùdánwò ti dán yín wò, kí akitiyan wa má baà já sí òfo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori eyi, nigbati ara mi kò gba a mọ́, mo si ranṣẹ ki emi ki o le mọ igbagbọ́ nyin ki oludanwò nì má bã ti dan nyin wo lọnakọna, ki lãlã wa si jẹ asan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí mo wí tẹ́lẹ̀, nígbà tí ara mi kò gba ìdákẹ́jẹ́ẹ́ náà, mo rán Tímótíù láti bẹ̀ yín wò, kí ó lè mọ̀ bóyá ìgbàgbọ́ yín sì dúró gbọn-ingbọn-in. Mo funra sí i wí pé, sàtánì ti ṣẹ́gun yín. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ wa (láàrin yín) jásí aṣán.