1 Thessalonians 3:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn nisinsinyii, Timoti ti ti ọ̀dọ̀ yín dé, ó ti fún wa ní ìròyìn rere nípa igbagbọ ati ìfẹ́ yín. Ó ní ẹ̀ ń ranti wa sí rere nígbà gbogbo, ati pé bí ọkàn yin ti ń fà wá, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ti àwa náà ń fà yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nisisiyi ti Timotiu ti ti ọdọ nyin wá sọdọ wa, ti o si ti mu ihinrere ti igbagbọ́ ati ifẹ nyin wá fun wa, ati pe ẹnyin nṣe iranti wa ni rere nigbagbogbo, ẹnyin si nfẹ gidigidi lati ri wa, bi awa pẹlu si ti nfẹ lati ri nyin:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísìnsinyìí, Tímótíù ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín sì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá. Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ sì ń rántí ìbágbé wa láàrin yín pẹ̀lú ayọ̀. Tímótíù tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá.