1 Thessalonians 4:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí nígbà tí ohùn àṣẹ bá dún, Olórí àwọn angẹli yóo fọhùn, fèrè Ọlọrun yóo dún, Oluwa fúnrarẹ̀ yóo sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Àwọn òkú ninu Jesu ni yóo kọ́kọ́ jinde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Oluwa tikararẹ̀ yio sọkalẹ lati ọrun wá ti on ti ariwo, pẹlu ohùn olori awọn angẹli, ati pẹlu ipè Ọlọrun; awọn okú ninu Kristi ni yio si kọ́ jinde:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé, Olúwa fúnraarẹ́ yóò sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá, pẹ̀lú ariwo àṣẹ ńlá àti ohùn àwọn ańgẹ́lì ti àwọn ańgẹ́lì ti àwọn ti ìpè Ọlọ́run, àwọn òkú nínú Kírísítì yóò sì kọ́kọ́ jíǹde.