1 Thessalonians 5:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn eniyan bá ń wí pé, “Àkókò alaafia ati ìrọ̀ra nìyí,” nígbà náà ni ìparun yóo dé bá wọn lójijì, wọn kò sì ní ríbi sá sí; yóo dàbí ìgbà tí obinrin bá lóyún, tí kò mọ ìgbà tí òun yóo bí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn ba nwipe, alafia ati ailewu; nigbana ni iparun ojijì yio de sori wọn gẹgẹ bi irọbi lori obinrin ti o lóyun; nwọn kì yio si le sálà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àláfíà àti àbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí rí ibi ààbò láti sá sí.