1 Timothy 1:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí mò ń lọ sí Masedonia, mo gbà ọ́ níyànjú pé kí o dúró ní Efesu, kí o pàṣẹ fún àwọn kan kí wọn má ṣe kọ́ eniyan ní ẹ̀kọ́ tí ń ṣini lọ́nà,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi mo ti gba ọ niyanju lati joko ni Efesu, nigbati mo nlọ si Makedonia, ki iwọ ki o le paṣẹ fun awọn kan, ki nwọn ki o máṣe kọ́ni li ẹkọ́ miran,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí mo se rọ̀yín nígbàtí mò ń lọ sí Makedóníà, ẹ dúró ní Éfésù, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́