1 Timothy 1:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
kí wọn má jókòó ti àwọn ìtàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ati ìtàn ìrandíran tí kò lópin, tí ó máa ń mú àríyànjiyàn wá, dípò ẹ̀kọ́ nípa Ọlọrun tí a mọ̀ nípa igbagbọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki nwọn má si ṣe fiyesi awọn itan lasan, ati ti ìran ti kò li opin, eyiti imã mú ijiyan wa dipo iṣẹ iriju Ọlọrun ti mbẹ ninu igbagbọ́; bẹni mo ṣe nisisiyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí wọ́n má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn-asán, àti ìtàn-ìran aláìlópin. Irú èyí máa ń mú iyàn jíjà wá dípò iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run èyí tí í ṣe ti ìgbàgbọ́.