1 Timothy 2:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bákan náà, kí àwọn obinrin wọ aṣọ bí ó ti yẹ, aṣọ tí kò ní ti eniyan lójú, kí wọ́n ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́ níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Kí wọn má ṣe di irun wọn ní aláràbarà fún àṣehàn. Kí wọn má ṣe kó ohun ọ̀ṣọ́ bíi wúrà ati ìlẹ̀kẹ̀ tabi aṣọ olówó ńlá sára.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ gẹgẹ ki awọn obinrin ki o fi aṣọ iwọntunwọnsin ṣe ara wọn li ọṣọ́, pẹlu itiju ati ìwa airekọja; kì iṣe pẹlu irun didì ati wura, tabi pearli, tabi aṣọ olowo iyebiye,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsí ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun-dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye,