1 Timothy 3:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nítorí bí mo bá pẹ́ kí n tó wá, kí o lè mọ̀ bí ó ti yẹ láti darí ètò ilé Ọlọrun, èyí tíí ṣe ìjọ Ọlọrun alààyè, òpó ati ààbò òtítọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi mo ba pẹ, ki iwọ ki o le mọ̀ bi o ti yẹ fun awọn enia lati mã huwa ninu ile Ọlọrun, ti iṣe ijọ Ọlọrun alãye, ọwọ̀n ati ipilẹ otitọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí mo bá pẹ́, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn láti máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run, tì í ṣe ìjọ Ọlọ́run, alààyè, ọ̀wọ́n àti ìpìlẹ̀ òtítọ́.