1 Timothy 3:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé àṣírí ẹ̀sìn wa jinlẹ̀ pupọ: Ẹni tí ó farahàn ninu ẹran-ara, tí a dá láre ninu ẹ̀mí, tí àwọn angẹli fi ojú rí, tí à ń waasu rẹ̀ láàrin àwọn alaigbagbọ, tí a gbàgbọ́ ninu ayé, tí a gbé lọ sinu ògo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Laiṣiyemeji, titobi ni ohun ijinlẹ ìwa-bi-Ọlọrun, ẹniti a fihan ninu ara, ti a dalare ninu Ẹmí, ti awọn angẹli ri, ti a wasu rẹ̀ lãrin awọn orilẹ-ede, ti a gbagbọ ninu aiye, ti a gba soke sinu ogo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láìṣiyè méjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run: ẹni tí a fi hàn nínú ara, tí a dáláre nínú Ẹ̀mí, ti àwọn ańgẹ́lì rí, tí a wàásù rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, tí a gbàgbọ́ nínú ayé, tí a sì gbà sókè sínú ògo.