1 Timothy 3:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, olùdarí níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn; kò gbọdọ̀ ní ju iyawo kan lọ, ó gbọdọ̀ jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ọlọ́gbọ́n eniyan, ọmọlúwàbí, ẹni tí ó fẹ́ràn láti máa ṣe eniyan lálejò, tí ó sì fẹ́ràn iṣẹ́ olùkọ́ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan, oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùsọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà yíyẹ, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́.