1 Timothy 4:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Eniyan a máa rí anfaani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá ti ara, ṣugbọn anfaani ti ẹ̀mí kò lópin; nítorí ó ní anfaani ní ayé yìí, ó tún fún eniyan ní anfaani ti ayé tí ń bọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ṣíṣe eré ìdaraya ní èrè diẹ, ṣugbọn ìwa-bi-Ọlọrun li ère fun ohun gbogbo, o ni ileri ti aiye isisiyi ati ti eyi ti mbọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwá-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti igbé-ayé ìṣinṣinyìí àti ti èyí tí ń bọ̀,