1 Timothy 5:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
tí a jẹ́rìí sí iṣẹ́ rere rẹ̀, tí ó tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dáradára, tí ó máa ń ṣe eniyan lálejò, tí kò sí iṣẹ́ tí ó kéré jù tí kò lè ṣe fún àwọn onigbagbọ, tí ó ti ran àwọn tí ó wà ninu ìyọnu lọ́wọ́. Ní kúkúrú, kí ó jẹ́ ẹni tí ń ṣe iṣẹ́ rere nígbà gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti a jẹri rẹ̀ fun iṣẹ rere; bi o ba ti ntọ́ ọmọ ri, bi o ba ti ngba alejò, bi o bá ti nwẹ ẹsẹ awọn enia mimọ́, bi o ba ti nràn awọn olupọnju lọwọ, bi o ba ti nlepa iṣẹ rere gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni ti a jẹ́rì rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹṣẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olupọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.