1 Timothy 5:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí onigbagbọ obinrin kan bá ní àwọn opó ninu ẹbí rẹ̀, òun ni ó níláti ṣe ìtọ́jú wọn. Kò níláti di ẹrù wọn lé ìjọ Ọlọrun lórí, kí ìjọ lè mójútó àwọn tí wọ́n jẹ́ opó gidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi obinrin kan ti o gbagbọ́ ba ni awọn opó, ki o mã ràn wọn lọwọ, ki a má si di ẹrù le ijọ, ki nwọn ki o le mã ràn awọn ti iṣe opó nitõtọ lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí ó gbàgbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a má sì di ẹrù lé ìjọ, kí wọn lè máa ran àwọn ti í ṣe opó nítòótọ́ lọ́wọ́.