1 Timothy 5:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí opó kan bá ní àwọn ọmọ tabi àwọn ọmọ-ọmọ, wọ́n gbọdọ̀ kọ́ láti ṣe ìtọ́jú ìdílé wọn, kí wọ́n san pada ninu ohun tí àwọn òbí wọn ti ṣe fún wọn. Èyí ni ohun tí ó dára lójú Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi opó kan ba li ọmọ tabi ọmọ-ọmọ, jẹ ki nwọn tète kọ́ ati ṣe itọju ile awọn tikarawọn, ki nwọn ki o si san õre awọn obi wọn pada: nitoripe eyi li o ṣe itẹwọgbà niwaju Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ni ọmọ tàbí ọmọ-ọmọ, jẹ́ kí wọn kọ́kọ́ kọ́ bí a ti ń ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkárawọn, kí wọn sì san oore àwọn òbí wọn padà; nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run.